Lẹ́yìn tó lo ọdún 42, wọ́n sọ fún ọkùnrin adúláwọ̀ kan pé kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì - BBC News Yorùbá (2024)

Lẹ́yìn tó lo ọdún 42, wọ́n sọ fún ọkùnrin adúláwọ̀ kan pé kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì - BBC News Yorùbá (1)

Osisẹ fẹyinti, ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin, to wa lati orilẹede Ghana, to ti n gbe ni ilẹ Uk fun o ku diẹ ko pe aadọtaa ọdun ni wọn ti ni ko duro ọdun mẹwaa ki wọn to le faye gba ko ma gbe ni UK ti ti lialia.

Nelson Shardey, ẹni to wa lati Wallasey ni Wirral lo ti lo ọpọlọpọ ọdun ni ilẹ UK pẹlu erongba pe oun ti di ọmọ ilu.

Sugbọn o ri pe ọrọ ko ri bẹ ni ọdun 2019, pẹlu bo ti lẹ jẹ pe o san owo ori.

Ni bayii n koju ipe pe o ni lati san ọpọlọpọ owo lati le duro ni ilẹ UK.

Ẹka ijọba Home Office kọ lati sọrọ lori igbẹjọ to n lọ lọwọ.

Igbawo ni Shardey de si ilẹ UK?

Shardey de si ilẹ UK ni ọdun 1977 lati wa kawe nipo imọ isiro, ti wọn si gba laaye pẹlu iwe irinna akẹkọọ sugbọn o ni anfani lati siṣẹ.

Lẹyin ti iditẹgbajọba waye ni orilẹede Ghana to ti wa, awọn mọlẹbi lo ri aye lati fowo ranṣẹ si mọ.

O bẹrẹ si ni ma ṣe orisirisi iṣẹ , bi burẹdi niluu Southampton, o n ta sokoleti ni Winchester, ti ẹnikẹni ko si sọ pe ko ni ẹtọ lati gbe ni ilẹ UK.

O fẹ ọmọ Ilẹ Gẹẹsi, to ko lọ wallasey lati da okowo rẹ silẹ, ileeṣẹ iroyin to pe ni Nelson News.

Nigba ti igbeyawo naa forisanpọn, o fẹ ọmọ ilẹ Gẹẹsi mii, ti wọn si bi ọmọ nmeji fun ara wọn, Jacob ati Aaron.

Lẹ́yìn tó lo ọdún 42, wọ́n sọ fún ọkùnrin adúláwọ̀ kan pé kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì - BBC News Yorùbá (2)

Oríṣun àwòrán, Nelson Shardey

“Mo gbiyanju agbara mi lati tọ awọn yii lati ri pe wọn ko wo ọwọ ọ lọwọ ki wọn to jẹun,” Shardey ṣalaye.

O sọ fun awọn ọmọ rẹ lati kọ ẹkọ, ki wọn le ri iṣẹ gidi, ti wọn yoo si le siṣẹ fun arawọn.

Awọn ọmọ naa ka ẹkọ de ilẹ ẹkọ fasiti, ti wọn si bẹrẹ gẹgẹ bii onimọ sayẹnsi ati osisẹ to n ba araalu sọrọ.

Shardey ni ko fi igba kankan kuro ni ilẹ UK, ti oun ko si ri idi ti oun ko fi le pe ni Ile oun.

“Ẹnikẹni ko bi mi ni ibeere. Awin ni mo ra gbogbo nnkan mi, ko ile mi.”

O gba ami ẹyẹ fun bi doola ẹmi ọkunrin kan ti adigunjale fẹ fọ igi mọ lori.

Sugbọn lọdun 2019, nigba to fẹ forukọ silẹ fun iwe irinna lati le pada si orilẹede Ghana lẹyin ti iya rẹ jade laye sugbọn wọn sọ fun pe ki ṣe ọmọ ilẹ Gẹẹsi.

Ẹka Home Office ni ko lẹtọ lati wa ilẹ UK.

Lẹ́yìn tó lo ọdún 42, wọ́n sọ fún ọkùnrin adúláwọ̀ kan pé kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì - BBC News Yorùbá (3)

Oríṣun àwòrán, Nelson Shardey

N ko ni agbara lati san owo ti wọn n bere fun

Owo ti yoo na lati forukọ silẹ jẹ égbẹrun meje poun, ti o le si lekun si ẹgbẹrun mẹwaa le diẹ owo poun lati le lo NHS.

“N ko ni agbara lati san eyikeyi owo ti wọn bere fun un,” Shardey ṣalaye.

“Sisọ fun mi pe ki lo ọna jẹ fiyajẹni, ti ko si tọna .”

“Gbogbo ariwo yii ni ko ye mi nitori mo fi ẹmi mi lelẹ fun orilẹede yii.”

Nigba to gbiyanju lati forukọ silẹ fun anfani lati duro ni Uk lọdun mẹji, o tọwọ odi.

Fun eyi, wọn ko ni fi aye gba Shardey lati duro ni ilẹ UK titi yoo fi di ẹni ọdun mẹrinlọgọrin.

“Awada ni mo pe. Eyi ko boju mu,” Jacob, ọkan lara ọmọ rẹ fẹhonuhan.

“Ki lo de ti yoo lọ fi orukọ fun ọdun mẹwaa nigba ti o ti wa ni ilu yii lati ọdun1977?.

“O ti wa lorilẹede saaju ki wọn to bi gbogbo awọn to wa ni ẹka Home Office.”

Ibo ni ọrọ de duro bayii?

Pẹlu iranlọwọ Nicola Burgess, agbẹjọro Greater Manchester Immigration, Shardey ti wa wọ ẹka Home Office lọ si ile ẹjọ.

Igbẹjọ naa ni awọn ọmọ rẹ n gbiyanju lati san owo rẹ, ti wọn si bẹrẹ fun iranlọwọ.

Bakan naa ẹjọ ti wọn pe ẹka Home Office ni pe ko yẹ ki wọn wu wa si Shardey bi wọn ṣe wu wa nitori o jẹ ẹnikan to ti pẹ ni ilu, to tun ni ami ẹyẹ fun iṣẹsẹ ribiribi.

Agbẹnusọ Home Office ni “Yoo lodi sofin lati sọrọ nipa ọrọ to wa ni ile ẹjọ.”

Lẹ́yìn tó lo ọdún 42, wọ́n sọ fún ọkùnrin adúláwọ̀ kan pé kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì - BBC News Yorùbá (2024)
Top Articles
Latest Posts
Article information

Author: Gov. Deandrea McKenzie

Last Updated:

Views: 5397

Rating: 4.6 / 5 (46 voted)

Reviews: 85% of readers found this page helpful

Author information

Name: Gov. Deandrea McKenzie

Birthday: 2001-01-17

Address: Suite 769 2454 Marsha Coves, Debbieton, MS 95002

Phone: +813077629322

Job: Real-Estate Executive

Hobby: Archery, Metal detecting, Kitesurfing, Genealogy, Kitesurfing, Calligraphy, Roller skating

Introduction: My name is Gov. Deandrea McKenzie, I am a spotless, clean, glamorous, sparkling, adventurous, nice, brainy person who loves writing and wants to share my knowledge and understanding with you.